CAC HYMN 023
Iwo Imole Okan mi
CAC Hymn 023
Iwo imole okan mi
- 1. Iwo imole okan mi,
- Ni odo Re, oru ko si,
- Ki kuku aye ma bo O,
- Kuro l'oju iranse Re.
- .
- 2. Ni gba t'orun ale didun
- Ba npa ipenpe 'ju mi de,
- K'ero mi je lati simi,
- Lae l'aya Olugbala mi.
- 3. Ba mi gbe l'oro tit'ale
- Laisi Re, emi ko le wa,
- Ba mi gbe 'gbat'ile ba nsu,
- Laisi Re, emi ko ke ku.
- .
- 4. Bi otosi omo Re kan
- Ba tapa s'oro Re loni,
- Oluwa, sise ore Re,
- Ma je k'o sun ninu ese
- 5. Bukun fun awon alaisan,
- Pese fun awon talaka,
- K'orun onirobinuje
- Dabi orun omo titun
- .
- 6. Sure fun wa ni gbat'a ji
- Ka to m'ohun aye yi se
- Titi awa o de 'b'ife
- T'a o si de Ijoba Re.
- .
- AMIN
CAC HYMN V001
Bukun le wa
CAC Hymn V001
Bukun 'le wa at'ebi wa
- 1. Bukun 'le wa at'ebi wa, at'ara wa/2ce
- Ibukun orun, iranwo, Re,
- Ibukun orun ko fi kari awa,
- K'O fi fun wa o, l'aye l'orun o,
- Baba orun
- .
- 2. Tu wa lara, Alagbara, se 'toju wa/2ce
- Itunu Re, alafia Re,
- Ike Re, K'O fi toju wa, ye,
- Awa mbe O o, gbo adura wa,
- Oba Ogo.
- .
- 3. Baba fun wa l'Emi mimo at'agbara/2ce
- Iranse orun, ebun lat'orun
- Itunu Baba, k'o wonu okan wa,
- K'o gbe 'nu wa o, k'o fun wa l'ayo,
- Oba Orun.
- .
- 4. Awa f'iyin at'ope fun Baba l'orun/2ce
- Iyin fun 'ranwo, ope fun anu,
- Ayo fun 'dasi ti a nri lojojo,
- Ope fun O o, a tun juba Re,
- Baba awa.
- Amin
CAC HYMN 339
Ke Kabiyesi
CAC Hymn 339
Ke kabiyesi
- 1. Ke Kabiyesi! gbe ilekun soke;
- Lenu ona re Oba Ogo nduro!
- Si okan re, si le ese jade,
- Dide jeki Oba Ogo wole.
- .
- Tali On? Tal'Oba Ogo yi?
- Jesu Oluwa li ola ye fun
- Ke Kabiyesi Wole n'waju Re
- Se l'Oba, l'Oba Oba gbogb'eda.
- .
- 2. Lati agbala orun lojo na,
- O sokale ni ara erupe;
- Fun wa n'ijiya, ibanuje Re,
- Ise irora ati ekun Re.
- .
- 3. A kan mo 'gi ika ati 'tiju
- F'eje Re ta ta 'le lo se w'aye;
- Gbo lat' enu re igbe irora,
- Nitori wa l'Olugbala se ku.
- .
- 4. Iku ko le bori Re niboji,
- Lowuro lo jade kuro nibe,
- O ji dide, O njoba ni oke,
- Ki gbogb'aye f'iyin fun Oluwa.
- Amin.
CAC HYMN 732
Jesus Mo Gb'agbelebu
CAC Hymn 732
Jesus Mo Gb'agbelebu
- 1. Jesu, mo gb'agbelebu mi
- Ki nle ma to O leyin;
- Otosi at'eni egan,
- 'Wo l'ohun gbogbo fun mi
- Bi ini mi gbogbo segbe
- Ti ero mi gbogbo pin
- Sibe, oloro ni mo je!
- T'emi ni Krist' at'orun.
- .
- 2. Eda le ma wahala mi,
- Y'o mu mi sunmo O ni;
- Idanwo aye le ba mi,
- Orun o mu 'simi wa,
- Ibanuje ko le se nkan
- Bi 'fe Re ba wa fun mi;
- Ayo ko si le dun mo mi
- B'iwo ko si ninu re
- .
- 3. Okan mi, gba igbala re;
- Bori ese at'eru;
- F'ayo wa ni ipokipo,
- Ma sise lo, ma weyin,
- Ro t'emi t'o wa ninu Re
- At' ife Baba si o!
- W'Olugbala t'O ku fun o
- Omo orun mase kun.
- .
- 4. Nje koja lat' ore s'ogo
- N'nu adura on 'gbagbo;
- Ojo ailopin wa fun O,
- Baba y'o mu o de 'be,
- Ise re l'aye fere pin
- Ojo ajo re nbuse,
- Ireti y'o pada 'sayo,
- Adura s'orin iyin.
- .
- Amin.
CAC HYMN V028
Igba Aye Wa a Ro
CAC Hymn V028
Igba Aye wa a ro
- 1. Igba aye wa a ro gbedegbede
- Igba aye wa a ro gbedegbede
- Ka sa li beru Oluwa Oba Ogo;
- Inu buruku, aso ka mu kuro;
- Ka toro fun suru, baba iwa ni;
- Igba aye wa a ro gbedegbede
- .
- 2. Igba aye wa a ro gbedegbede;
- Igba aye wa a ro gbedegbede
- K'a ma se f'iwa ipa so ara wa degbin;
- Ejo elejo, odi, ka mu kuro;
- K'a yera fun rigimo ipa osi ni;
- Igba aye wa a ro gbedegbede.
- .
- 3. Igba aye wa ro gbedegbede;
- Igba aye wa a ro gbedegbede
- Ka sa ma yo n'nu Oluwa k'a wa Ogbon;
- Ife inu 're, ayo ka fi josin
- K'ododo kun emi wa, ipa iye ni;
- Igba aye wa a ro gbedegbede.
- .
- 4. Igba aiye wa a ro gbedegbede;
- Igba aye wa a ro gbedegbede
- K'ani ife bi Olorun ti se fe wa;
- Ati bi t' alanu ara Samaria;
- Pelu 'reti to daju ni aye ti mbo;
- Igbe aye wa ro gbedegbede
- Amin.
CAC HYMN 188
Elese Eyi Pada
CAC Hymn 188
Elese Eyi Pada
- 1. Elese, e yipada,
- Ese ti e o fi ku?
- Eleda yin ni mbere
- Tofeki e ba On gbe;
- Oran nla ni O mbi yin,
- Ise owo Re ni yin;
- A! eyin alailope
- Ese t' e o ko 'fe Re?
- .
- 2. Elese e yi pada,
- Ese ti o o fi ku?
- Olugbala ni mbere;
- Eni t'O gb'emi yin la;
- Iku Re y'o j'asan bi?
- E o tun kan mo 'gi bi?
- Eni 'rapada ese
- Te o gan or'ofe Re?
- .
- 3. Elese, e yi pada,
- Ese ti e o fi ku?
- Emi mimo ni mbere
- Ti nfojo gbogbo ro yin;
- E ki o ha gb'ore Re?
- E o ko iye sibe?
- Ati nwa yin pe, ese
- T'e mbi Olorun ninu?
- .
- 4. Iyemeji ha nse yin
- Pe ife ni Olorun
- E ki o ha gboro Re?
- K'e gba ileri Re gbo?
- W'Oluwa lodo yin,
- Jesu sun, w'omije Re;
- Eje Re pelu nke pe:
- Ese ti e o fi ku?
- .
- Amin.
CAC HYMN 398
Jesu Yio Gba Elese
CAC Hymn 398
Jesu Yio Gba Elese
- 1. Jesu y'o gba elese
- Kede re fun gbogb' eda;
- Awon ti won sako lo,
- Awon ti won ti subu.
- .
- Ko l'orin, ko si tun ko
- Kristi ngb' awon elese
- Fi oto na ye won pe:
- Kristi ngb' awon elese
- .
- 2. Wa, y'o fun o ni 'simi;
- Gbagbo, oro Re daju,
- Y'o gba eni buru ju;
- Kristi ngb' awon elese
- .
- 3. Okan mi da mi lare,
- Mo mo niwaju ofin;
- Eni t'O ti we mi mo,
- Ti san gbogbo 'gbese mi.
- .
- 4. Kristi ngb' awon elese
- An' emi to kun f'ese
- O ti so mi di mimo;
- Mo ba wo 'joba Orun;
- Amin.
CAC HYMN 206
Iye Wa Ni Wiwo
CAC Hymn 206
Iye Wa Ni Wiwo
- 1. Iye wa ni wiwo Eni t'a kan mo 'gi,
- Iye wa nisisiyi fun o;
- Nje wo O elese k'o le ri 'gbala
- Wo Eni t'a kan mo 'gi fun o
- -
- Wo! wo! wo, k'o ye,
- Iye wa ni wiwo, Eni t'a kan mo 'gi
- Iye wa nisisiyi funo.
- -
- 2. Kini On se wa bi eleru ese
- Ba ko ba gb'ebi re ru Jesu!
- Eje 'wenumo ha se ti iha Re san,
- Bi 'ku Re ko ba san gbese re?
- -
- 3. Ki' s'ekun 'piwada ati t'adura re,
- Eje na lo s'etutu f'okan,
- Gbe eru ese re lo si odo Eni
- Ti o ti ta eje na sile.
- -
- 4. Ma siyemeji s'ohun ti Olorun wi
- Ko s'ohun to ku lati se mo
- Ati pe Oun yio wa nikeyin aye,
- Y'o si s'ase pari ise Re
- -
- 5. Nje wa fayo gba iye ainipekun
- Ni owo Jesu ti fi fun ni;
- Si mo daju pe iwo ko le ku laelae
- Gbati Jesu ododo re wa.
- Amin.
CAC HYMN 869
Ojo nla lojo lojo ti mo yan
CAC Hymn 869
Ojo Nla Lojo Ti Mo Yan
- 1. Ojo nla l'ojo ti mo yan
- Olugbala l'Olorun mi;
- O ye ki okan mi ma yo,
- K'o si ro ihin na kale
- -
- Ojo nla l'ojo na
- Ti Jesu we ese mi nu;
- O ko mi ki nma gbadura
- Ki nma sora, ki nsi ma yo,
- Ojo nla l'ojo na
- Ti Jesu we ese mi nu.
- -
- 2. Ise igbala pari na,
- Mo di t'Oluwa mi loni;
- On l'o pe mi, ti mo si je,
- Mo f'ayo j'ipe mimo na.
- -
- 3. Eje mimo yi ni mo je
- F'eni to ye lati feran:
- Je k'orin didun kun 'le RE
- Nigba mo ba nlo sin nibe
- -
- 4. Simi, aiduro okan mi,
- Simi le Jesu Oluwa;
- Tani je wipe aye dun,
- Ju odo awon angeli?
- -
- 5. 'Wo orun t o ngbo eje mi,
- Y'o ma tun gbo lojojumo,
- Tit' ojo t'emi mi y'o pin
- Ni uno ma m'eje mi na se
- Amin.
CAC HYMN 478
Mo Yo Pupo Pe Baba Wa Orun
CAC Hymn 478
Mo Yo Pupo Pe Baba Wa Orun
- 1. Mo yo pupo pe Baba wa orun
- So t'ife Re ninu 'we t'O fun mi,
- Mo r'ohun 'yanu ninu Bibeli,
- Eyi s'owon ju pe, Jesu fe mi.
- -
- Mo yo pupo pe Jesu fe mi,
- Jesu fe mi, Jesu fe mi,
- Mo yo pupo pe Jesu fe mi,
- Jesu fe an'emi.
- -
- 2. 'Gba mo gbagbe Re, ti emi sa lo,
- O fe mi sibe, O wa mi kiri;
- Mo yara pada s'apa anu Re,
- 'Gbati mo ranti pe Jesu fe mi.
- -
- 3. Bi o se orin kan l'emi le ko,
- 'Gba mo r'Oba nla ninu ewa Re;
- Eyi ni yo ma j'orin mi titi,
- A! iyanu ni pe, Jesu fe mi.
- -
- 4. Jesu fe mi, mo si mo pe mo f'E,
- Ife lo mu wa r'okan mi pada
- Ife lo m'U k'o ku l'ori igi
- O da mi loju pe, Jesu fe mi.
- -
- 5. Emi o ti se dahun b'a bi mi
- Ohun ti ogo Oluwa mi je?
- Emi mimo njeri nin'okan mi,
- Ni igba gbogbo pe, Jesu fe mi.
- -
- 6. Ni 'gbekele yi ni mo r'isimi,
- Ni 'gbekele Krist' mo d'alabukun,
- Satan damu sa kuro l'okan mi,
- Nigba mo so fun pe, Jesu fe mi.
- Amin.
CAC HYMN 767
Gbo Iro Li Opopo Aiye
CAC Hymn 767
Gbo Iro Li Opopo Aiye
- 1. Gbo iro li opopo aye
- Bi ti igbi omi okun,
- Ti nfi agbara re ru s'oke
- T'o si nkolu ebute.
- -
- Gbo iro ese omo ogun
- Bi won ti nrin lo li ona na,
- Are mu won fun 'se at'irin ajo
- Ati ija kikoro;
- Sugbon won gbagbo, won tejumo
- Ona na t'awon mimo ti nrin,
- Bi won ti nlo ni 'gbagbo
- Won ndagba n'nu Olorun Alaye
- -
- 2. Won ntesiwaju pelu 'gbagbo
- Ti ekokeko ko le mi;
- Won gbagbo pe oro Olorun
- Le pese f'aini gbogbo.
- -
- 3. Dapo mo won, aye wa sibe,
- Duro de 'bukun Olorun;
- Oun ni 'reti gbogbo agbaye
- Lati sise ododo.
- Amin.
CAC HYMN 082
Yin Oluwa
CAC Hymn 082
Yin Oluwa
- 1. Gbogbo eyin ti ngbe aye
- E f'ayo korin s'Oluwa;
- F'iberu sin, e yin l'ogo
- E wa s'odo Re, k'e si yo.
- -
- Yin Oluwa 2x
- Yin Oluwa Olorun Agbaye o
- Yin Oluwa 2x
- Yin Oba Ainipekun
- -
- 2. Oluwa, On ni Qlorun,
- Laisi 'ranwo wa O da wa;
- Agbo Re ni wa, O mbo wa;
- O si fi wa s'agutan Re.
- -
- 3. Nje, f'iyin wo ile Re wa
- F'ayo sunmo agbala Re;
- Yin, k'e bukun oruko Re,
- 'Tori o ye be lati se.
- -
- 4. Ese? rere l'Olorun wa,
- Anu Re o wa titi lae,
- Oto Re ko fi 'gbakan ye,
- O duro lat' irandiran.
- -
- Amin.
CAC HYMN 284
Isun kan wa to kun feje
CAC Hymn 284
Isun Kan wa to kun feje
- 1. Isun kan wa to kun feje,
- T'o ti'ha Jesu yo;
- Elese mokun ninu re,
- O bo ninu ebi.
- -
- A sa l'ogbe, n'tori 'rekoja,
- A si pa lara, n'tori ese wa,
- Ina alafia wa mbe l'ara Re
- Ina Re lo nwo wa san;
- A sa l'ogbe n'tori 'rekoja,
- A sa l'ogbe n'tori 'rekoja,
- Ina Re lo nwo wa san,
- Ina Re nwo wa san.
- -
- 2. Ole ni lor'agbelebu,
- Yo lati ri 'sun na,
- Bi mo kun f'ese bi tire,
- Mo le we n'n' eje na.
- -
- 3. Gba mo figbagbo r'isun na
- Ti nsan fun eje Re
- Irapada d'orin fun mi,
- Ti un o ma ko titi.
- -
- 4. Agbara to wa n'n' eje yi
- Yo wa titi laelae,
- Tit'won eni 'rapada,
- Yo bo sinu ogo.
- Amin.
CAC HYMN V003
Okan Mi Yin Oluwa Logo
CAC Hymn V003
Okan Mi Yin Oluwa Logo
- 1. Okan mi yin Oluwa logo,
- Oba iyanu t'O wa mi ri:
- Uno l'agogo iyin y'aye ka
- Uno si fife Atobiju han
- -
- Oluwa, ope ni fun O
- Fun ore-ofe t'O fi yan mi,
- Jowo dimi mu titi dopin
- Ki nle joba pelu Re loke
- -
- 2. Bi eranko l'emi ba segbe
- Bikose ti Oyigiyigi;
- Lairotele l'Emi Mimo de
- T'O f'ede titun si mi l'enu
- -
- 3. Ayo okan mi ko se rohin
- Loro, losan, loganjo oru;
- Gbat' Emi Mimo ti de 'nu mi
- Mo nkorin orun lojojumo
- -
- 4. Jesu ti la mi loju emi,
- Mo si f'eti gbohun ijinle
- O nse faji ninu okan mi;
- Kini mba fi fun Olugbala?
- -
- 5. Em'o sogo ninu Oluwa
- K'emi ma ba di alaimore;
- B'O ti pe mi iyanu l'o je
- Awon angel d'olulufe mi
- -
- 6. Mo damure lati sin Jesu
- Lai f'ota pe larin aye yi;
- Nibikibi t'O ba nto mi si
- O daju ko ni jeki ndamu
- -
- 7. Bi mba pari 're-ije l'aye,
- Olugbala, ma je ki npofo;
- Ni wakati na jeki ngbo pe,
- Bo sinu ayo ayeraye
- Amin
CAC HYMN 029
Oluwa Ojo to Fun Wa Pin
CAC Hymn 029
Oluwa Ojo to Fun Wa Pin
- 1. Oluwa, ojo to fun wa pin,
- Okunkun si de l'ase Re,
- 'Wo l'a korin owuro wa si,
- Iyin Re y'o m'ale wa dun.
- -
- 2. A dupe ti ijo Re ko sun,
- B'aye ti nyi lo s'imole,
- O si nsona ni gbogbo aye,
- Ko si simi t'osan-t'oru.
- -
- 3. B'ile si ti nmo l'ojojumo,
- Ni orile at'ekusu,
- Ohun adura ko dake ri,
- Be l'orin iyin ko dekun
- -
- 4. Orun t'o wo fun wa, si ti la,
- S'awon eda iwo-oorun,
- Nigbakugba li enu si nso
- Ise 'yanu Re di mimo
- -
- 5. Be, Oluwa, lae n'Ijoba Re,
- Ko dabi ijoba aye;
- O duro, o si nse akoso,
- Tit' eda Re o juba Re.
- AMIN
CAC HYMN 349
Bugbe Re Ti Lewa To
CAC Hymn 349
Bugbe Re Ti Lewa To
- 1. Bugbe Re ti l'ewa to
- N'ile 'mole at'ife!
- 'Bugbe Re ti l'ewa to
- L'aye ese at'osi!
- Okan mi nfa ni toto
- Fun idapo eeyan Re
- Fun imole oju Re
- Fun ekun Re Olorun.
- -
- 2. Ayo ba awon eye
- Ti nfo yi pepe Re ka,
- Ayo okan t'o nsimi
- L'aya Baba l'o poju,
- Gege b'adaba Noa
- Ti ko r'ibi simi le,
- Won pada s'odo Baba
- Won si nyo titi aye.
- -
- 3. Won ko simi iyin won
- Ninu aye osi yi;
- Omi sun ni aginju,
- Manna nt'orun wa fun won
- Won nlo lat' ipa de 'pa
- Titi won fi yo si O;
- Won si wole l'ese Re
- T'o mu won la ewu ja.
- -
- 4. Baba, je ki njere be;
- S'amona mi l'aye yi;
- F'ore-ofe pa mi mo;
- Fun mi l'aye l'odo Re;
- Iwo l'orun, at'asa;
- To okan isina mi,
- Iwo l'orisun ore,
- Ro ojo Re s'ori mi.
- Amin.
CAC HYMN V02
Emi Yio Gbadura Soba Mi
CAC Hymn V02
Emi Yio Gbadura Soba Mi
- 1. Emi y'o gbadura s'Oba mi, Edumare,
- Baba, ye ko wa gba mi o e;
- Okansoso Ajanaku,
- Wa pelu mi, ye Baba o
- -
- Emi, omo Re, nkepe O o,
- Baba, wa duro gbo
- -
- 2. Emi y'o gbadura s'Oba mi, Edumare,
- Baba, ma fi mi sile o e;
- Ran mi lowo Olubukun,
- Wa sike mi nile Re o
- -
- 3. Emi y'o gbadura s'Oba mi, Baba rere,
- Ma jek'emi padanu o e;
- Iwo ni Oba aiku
- Wa pade mi n'ile Re o
- -
- 4. Emi y'o gbadura s'Oba mi, Edumare
- Baba, wa fun mi l'ere o e;
- Okansoso Ajanaku,
- Ye bukun mi n'ile Re o
- Amin.
CAC HYMN 050
K'ojo Simi Yi to Tan
CAC Hymn 050
K'ojo Simi Yi to Tan
- 1. K'ojo 'simi yi to tan,
- K'a to lo f'ara le le,
- Awa wole lese Re,
- A nkorin iyin si O.
- -
- 2. Fun anu ojo oni,
- Fun isimi l'ona wa,
- 'Wo nikan l'a f'ope fun,
- Oluwa at'Oba wa,
- -
- 3. Isin wa ko nilari
- Aura wa lu m'ese,
- Sugbon 'Wo l'o nf'ese ji
- Or-ofe Re to fun wa.
- -
- 4. Je k'ife Re ma to wa,
- B'a ti nrin 'nu aye yi,
- Nigbat'ajo wa ba pin,
- K'a le simi l'odo Re.
- -
- 5. K'ojo 'simi wonyi je
- Ibere ayo orun,
- B'a ti nrin ajo wa lo
- Si 'simi ti ko lopin.
- AMIN
CAC HYMN 874
Moti Ni Jesu Lore
CAC Hymn 874
Moti Ni Jesu Lore
- 1. Mo ti ni Jesu l'ore, O j'ohun gbogbo fun mi;
- Oun nikan l'Arewa ti okan mi fe,
- Oun n'itanna ipado, On ni Enikan na
- T'O le we mi nu kuro n'nu ese mi
- Olutunu mi l'O je n'nu gbogbo wahala
- Oun ni ki n k'aniyan mi l'Oun lori,
- Oun ni Itanna Ipado, Irawp owuro,
- Oun nikan l'Arewa ti okan mi fe
- -
- Olutunu mi l'O je, n'nu gbogbo wahala
- Oun ni ki nk'aniyan mi l'On lori;
- Oun ni Itanna ipado, Irawo owuro,
- Oun nikan l'Arewa ti okan mi fe.
- -
- 2. O gbe gbogbo 'banuje at'irora mi ru,
- O j'odi agbara mi n'igba 'danwo;
- 'Tori Re mo k'ohun gbogbo ti mo ti fe sile,
- O si f'agbara Re gbe okan mi ro;
- Bi aye tile ko mi, ti Satani dan mi wo,
- Jesu yo mu mi d'opin irin mi;
- Oun ni itanna ipado, irawo owuro,
- Oun nikan l'Arewa ti okan mi fe.
- -
- 3. Oun ki y'o fi mi sile, be k'y'o ko mi nihin,
- Niwon ti nba fi 'gbagbo p'afin Re mo;
- O j'odi 'na yi ma ka, n ki y'o berukeru,
- Y'o fi manna Re b'okan mi t'ebi npa,
- 'Gba mba d'ade n'ikeyin, uno r'oju 'bukun Re,
- Ti adun Re y'o ma san titi lae,
- Oun ni Itanna Ipado, irawo owuro,
- Oun nikan l'Arewa ti okan mi fe
- Amin.
CAC HYMN 093
Ogo ni f'Oluwa to se ohun nla
CAC Hymn 093
Ogo ni f'Oluwa to se ohun nla
- 1. Ogo ni f'Oluwa to se ohun nla
- Ife lo mu k'O fun wa ni OmO Re,
- Enit'O f'emi Re lele f'ese wa
- To si silekun iye sile fun wa.
- -
- Yin Oluwa, Yin Oluwa,
- F'iyin fun Oluwa,
- Yin Oluwa, Yin Oluwa,
- E yo niwaju Re,
- Ka to Baba wa lo l'Oruko Jesu,
- Je k'a jo f'ogo fun Onise-yanu.
- -
- 2. Irapada kikun ti eje Re ra
- F'enikeni t'o gba ileri Re gbo,
- Enit'o buruju b'o ba le gbagbo,
- Lojukanna y'o ri idariji gba.
- -
- 3. O s'ohun nla fun wa, O da wa l'ola
- Ayo wa di kikun ninu Omo Re
- Ogo ati ewa irapada yi
- Y'o ya wa lenu 'gbat' a ba ri Jesu
- Amin.
CAC HYMN 660
Adupe Oluwa
CAC Hymn 660
Adupe Oluwa
- 1. Adupe Oluwa
- F'ajodun oni,
- O da emi wa si,
- Ogo f'oko Re;
- Pelu orin ayo
- L'a o fi josin
- Fun'bukun aye wa
- On 'reti orun.
- -
- Ajodun de, e yo!
- Ke, Aleluya!
- A m'ore ope wa,
- Tewo gb'ore wa.
- -
- 2. Opo l'elegbe wa
- Ni ko tun si mo;
- Opo ti sako lo
- Kuro lodo Krist'
- A dupe Oluwa
- Pe O da wa si,
- O si tun ka wa ye
- F'ajodun oni.
- -
- 3. Baba wa li orun,
- Awa se 'pinu
- Pe a o sin Jesu
- L'ojo aye wa,
- Ao sise fun 'dagba
- Soke ijo wa
- Tit' ao fi je 'pe Re
- Fun 'simi orun.
- -
- 4. 'Wo Oluw' ajodun
- A fope fun O,
- Je k'ire ajodun
- Kari gbogbo wa;
- A be O, Olorun,
- Fun wa l'agbara
- Lati sin O d'opin
- Ojo aye wa.
- Amin.
CAC HYMN V26
Mo Nte Siwaju
CAC Hymn V26
Mo Nte Siwaju
- 1. Mo ntesiwaju l'ona na
- Mo ngoke si lojojumo
- Mo gbadura bi mo ti nlo
- Oluwa jo gbe mi soke,
- -
- Oluwa, jo gbe mi soke
- Fa mi lo si ibi giga
- Apata t'o ga ju mi lo
- Oluwa jo gbe mi soke.
- -
- 2. Ife okan mi ko kuro
- Larin 'yemeji at'eru
- Awon miran le ma gbe be
- Ibi giga l'okan mi nfe
- -
- 3. Mo fe ki nga ju aye lo
- B'esu tile ngbogun ti mi
- Mo nfi gbagbo gbo orin na
- Ti awon mimo nko loke.
- -
- 4. Mo fe de 'bi giga julo
- Ninu ogo didan julo
- Mo ngbadura ki nle de be
- Oluwa mu mi de 'le na.
- -
- 5. Fa mi lo si ibi giga
- Laisi Re nko ni le de 'be
- Fa mi titi d' oke orun
- Ki nkorin lati 'ibi giga.
- Amin.
CAC HYMN 044
Ojo 'Simi At'ayo
CAC Hymn 044
Ojo Sinmi At'ayo
- 1. Ojo 'simi at'ayo
- Ojo inu didun,
- Itunu fun 'banuje
- Ojo dida julo,
- Ti awon eni giga
- Niwaju ite Re,
- Nko Mimo, Mimo, Mimo,
- S'Eni Metalokan.
- -
- 2. L'ojo yi n'imole la,
- Nigba dida aye,
- Ati fun igbala wa,
- Krist' jinde n'nu oku
- L'ojo yi li Oluwa
- Kan Emi t'orun wa,
- Ojo Ologo julo
- T'a tan 'mole pipe
- -
- 3. Ebute abo ni O
- Larin iji aye;
- Ogba didara ni O
- Nib'omi iye nsan
- Orisun 'tura ni O
- Laye aginju yi;
- L'ori re, bi ni pisga
- L'a nwo 'le ileri.
- -
- 4. L'oni s'ilu t'ara nu
- Ni manna t'orun nbo
- Si ipejopo mimo
- N'ipe fadaka ndun,
- N'ibiti ihinrere
- Ntan imole mimo
- Omi iye nsan jeje
- Ti ntu okan lara.
- -
- 5. K'a r'ore-ofe titun
- L'ojo 'simi wa yi
- K'a si de 'simi t'o ku
- F'awon alabukun,
- Nibe k'a gbo 'hun soke
- Si Baba at'Omo;
- Ati si Emi Mimo
- N'iyin Metalokan.
- AMIN
CAC HYMN 347
Olorun Wa Nbe Larin Wa
CAC Hymn 347
Olorun Wa Nbe Larin Wa
- 1. Olorun wa mbe larin wa,
- Lati bukun gbogbo wa,
- Wo oju orun b'o ti su
- Yo ro ojo ibukun;
- -
- K'o de Oluwa, a be O
- Je k'ojo Ibukun de;
- Awa nduro, awa nduro,
- M'okan gbogbo wa soji
- -
- 2. Olorun wa mbe larin wa
- Ninu ile mimo yi,
- Sugbon a nfe 'tura okan
- At'opo or'ofe Re
- -
- 3. Olorun wa mbe larin wa,
- K'a mu ebe wa t'O wa,
- Ki ife Re ba le gberan
- Lati m'okan wa gbona.
- -
- 4. Jesu fi 'bere wa fun wa,
- B'a ti f' igbagbo kunle,
- Jo si ferese anu Re
- K'o tu 'bukun sori wa.
- Amin.
CAC HYMN 242
Oluwa Emi Sa Ti Gbohun Re
CAC Hymn 242
Oluwa Emi Sa Ti Gbohun Re
- 1. Oluwa, emi sa ti gb' ohun Re
- O nso ife Re simi,
- Sugbon mo fe nde l' apa igbagbo
- Ki nle tubo sun mo O,
- -
- Fa mi mora, mora, Oluwa
- Sib' agbelebu t'O ku
- Fa mi mora, mora, mora Oluwa
- Sib' eje Re t'on'iye.
- -
- 2. Ya mi si mimo fun ise Tire,
- Nipa ore-ofe Re,
- Je ki nfi okan igbagbo w' oke
- K' ife mi'si je Tire,
- -
- 3. A! ayo mimo ti wakati kan
- Ti mo lo nib' ite Re;
- 'Gba mo ngb' adura si O, Olorun
- Ti a soro bi ore
- -
- 4. Ijinle ife mbe ti nko le mo
- 'Titi un"o koja odo
- Ayo giga ti emi ko le so
- Titi uno fi de 'simi
- Amin
CAC HYMN 140
Oluwa Nbo Aiye Yio Mi
CAC Hymn 140
Oluwa Nbo Aiye Yio Mi
- 1. Oluwa mbo; aye yo mi,
- Oke y'o sidi n'ipo won;
- At' irawo oju orun,
- Y'o mu imole won kuro.
- -
- 2. Oluwa mbo; bakanna ko
- Bi o ti wa n'irele ri;
- Odo-agutan ti a pa,
- Eni-iya ti o si ku.
- -
- 3. Oluwa mbo; li eru nla,
- L'owo ina pelu ija
- L'or' iye apa Kerubu,
- Mbo, Onidajo araye
- -
- 4. Eyi ha li eniti nrin,
- Bi ero l'opopo aye?
- Ti a se 'nunibini si?
- A! Eni ti a pa l'eyi?
- -
- 5. Ika b'e wo 'nu apata,
- B'e wo 'nu iho, lasan ni;
- Sugbon igbagbo t'o segun,
- Y'o korin pe, Oluwa de.
- Amin
CAC HYMN 059
Ose Ose Rere
CAC Hymn 059
Ose Ose Rere
- 1. Ose, oso rere,
- Iwo ojo simi;
- O ye k'a fi ojo kan
- Fun Olorun rere;
- B'ojo mi ba m'ekun wa,
- Iwo n' oju wa nu;
- Iwo ti s'ojo ayo,
- Emi fe dide re
- -
- 2. Ose Ose rere,
- A k'yo sise loni;
- A o f'ise wa gbogbo
- Fun aisimi ola,
- Didan l'oju re ma dan,
- 'Wo arewa ojo;
- Ojo mi nso ti lala,
- Iwo nso ti simi.
- -
- 3. Ose, Ose rere
- Ago tile nwipe,
- F'Eleda re l'ojo kan,
- T'O fun o n'ijo mefa;
- A o fi 'se wa sile,
- Lati lo sun nibe
- Awa ati ore wa;
- Ao lo sile adua
- -
- 4. Ose, Ose rere,
- Wakati re wu mi;
- Ojo orun ni 'wo se;
- "Wo apere orun;
- Oluwa, je ki njogun
- 'Simi leyin iku;
- Ki nle ma sin O titi,
- Pelu eniyan Re.
- AMIN
CAC HYMN 655
Wa Eyin Olope Wa
CAC Hymn 655
Wa Eyin Olope Wa
- 1. Wa, eyin Olope wa,
- Gbe orin ikore ga,
- Ire gbogbo ti wole
- K'otutu oye to de;
- Olorun Eleda wa,
- L'o ti pese f'aini wa;
- Wa k'a rele Olorun
- Gbe orin ikore ga.
- -
- 2. Oko Olorun l'a je
- Lati s'eso iyin Re
- Alikama at'epo,
- Ndagba f'aro tab' ayo
- Ehu yo, ipe tele
- Siri oka si kehin;
- Oluwa 'kore mu wa
- Je eso rere fun O.
- -
- 3. N'tori Olorun wa mbo
- Y'o si kore Re sile;
- On o gbon gbogbo panti
- Kuro l'oko re da nu;
- Y'o f'ase f'awon angel'
- Lati gba epo s'ina;
- Lati ko Alikama
- Si aba Re titi lae.
- -
- 4. Beni, maa bo, Oluwa
- Si ikore, ikeyin
- Ko awon eeyan Re jo
- Kuro l'ese at'aro;
- So won di mimo laelae
- Ki won le ma ba O gbe
- Wa t' Iwo t'angeli Re
- Gbe orin ikore ga.
- Amin.
CAC HYMN V07
Emi Yio San Ore
CAC Hymn V07
Emi Yio San Ore
- 1. Emi y'o san ore o f'Olorun mi)2x
- Eni da mi si o latesi wa )2x
- Fun jije, fun mimu, t'o n b'asiri mi
- Fun ipese lojojumo l'ona ara jaburata
- Ko je k'aye yo mi, loju elegan, aye mi Dara
- Emi y'o fore han f'Olorun mi.
- -
- 2. E jek' asajoyo f'ope oni)
- Eni ba m'ore Re waka s'ope )2x
- F'ori wa to dara, ti O nbukun fun wa
- O fi'gbala da wa lola, O npese ohun gbogbo
- Ko jek' awa segbe, loju elegan, O gbe wa ro o
- Eni 'nu re ba dun je ko yo o.
- -
- 3. Emi y'o yin Jesu, Oba Ogo)
- Olu seun ara, O m'ayo mi kun )2x
- O da mi lola o, O tun pe mi l'omo
- O f'ohun atata le mi lowo, ohun ijinle to daju
- Ko jek' eru ba mi, loju elegan o ye mi si o
- Emi y'o yin Jesu, Oba ogo.
- -
- 4. E je k'a fope han f'Olorun wa)
- Eni da wa si o d'ojo oni )2x
- O fun wa logbon o, O tun pe wa sagbo
- Omo Igbala mura giri, ko ma foya rara rara
- Duro ninu 'gbagbo, lojo aye re, a dara fun o
- E jek'a f ope han f'Olorun wa.
- Amin.
CAC HYMN 310
Gba Ti Mo Ri Agbelebu
CAC Hymn 310
Gba Ti Mo Ri Agbelebu
- 1. “Gbati mo ri agbelebu
- Ti a kan Oba Ogo mo
- Mo ka gbogbo oro s'ofo
- Mo kegan gbogbo ogo mi.
- -
- 2. K'a mase gbo pe mo nhale
- B'o ye n'iku Oluwa mi
- Gbogbo nkan asan ti mo fe
- Mo da sile fun eje Re
- -
- 3. Wo, lat' ori, owo, ese
- B'ikanu at' ife ti nsan;
- 'Banuje at' ife papo,
- A fegun se ade ogo
- -
- 4. Gbogbo aye 'baje t'emi.
- Ebun abere ni fun mi;
- Ife nla ti nyanilenu
- Gba gbogbo okan, emi mi.
- Amin.
CAC HYMN 288
Gbogbo Ogo Iyin
CAC Hymn 288
Gbogbo Ogo Iyin
- Gbogb' ogo, iyin, ola
- Fun O Oludande,
- S'Eni t'awon omode
- Nko Hosanna didun!
- 1. 'Wo l'Oba Israeli,
- Om'alade Dafid'
- T'O wa l'oko Oluwa;
- Oba Olubukun,
- -
- 2. Egbe awon Maleka
- Nyin O l'oke giga;
- Awa at'eda gbogbo
- Ni dapo gbe "rin na.
- -
- 3. Awon Heb'ru lo s'aju
- Pelu imo 0pe;
- Iyin, adua at'orin
- L'a mu wa 'waju Re
- -
- 4. Si O s'aju iya Re,
- Won korin iyin won!
- 'Wo t'a gbega nisiyi
- L'a nkorin iyin si.
- -
- 5. 'Wo gba orin iyin won,
- Gb'adura t'a mu wa,
- 'Wo ti nyo s'ohun rere,
- Oba wa Olore,
- Amin.
CAC HYMN 509
Ife Pipe to Tayo Ero Eda
CAC Hymn 509
Ife Pipe to Tayo Ero Eda
- 1. Ife pipe, t'o tayo ero eda,
- Niwaju Re l'a wole l'adura
- Pe, ki ife ailopin le je t'awon
- Ti Iwo so d'okan titi aye.
- -
- 2. Iye pipe, ma je igbekele won
- Fun ife on igbagbo ododo;
- Fun ireti on emi ifarada,
- Pelu 'fokantan lai beru iku.
- -
- 3. Fun won l'ayo ti nbori ibanuje
- Fun won l'alafia ti nm'aye dun,
- Titi owuro ologo y'o fi mo;
- Ojo ife on iye ailopin.
- Amin
CAC HYMN 009
Jesu Orun Ododo
CAC Hymn 009
Jesu Orun Ododo
- 1. Jesu, Orun ododo,
- Iwo imole ife
- Gbati 'mole Owuro,
- Ba nt'ila orun tan wa,
- Tan 'mole ododo Re
- Yi wa ka
- -
- 2. Gege be iri ti nse,
- S'ori eweko gbogbo,
- K'Emi ore-ofe Re
- S'o okan wa di otun,
- Ro ojo ibukun Re
- Sori Wa
- -
- 3. B'imole orun ti nran,
- K'imole ife Tire
- Si ma gbona l'okan wa,
- K'o si mu wa l'ara ya
- K'a le ma f'ayo sin O.
- L'aye wa.
- -
- 4. Amona ireti wa,
- Ma fi wa sile titi,
- Fi wa s'abe iso Re
- Titi opin emi wa,
- Sin wa la ajo wa ja
- S'ile wa
- -
- 5. Ma to wa l'ona toro
- L'ojo aye wa gbogbo
- Sin wa la ekun re ja,
- Mu wa de 'le ayo na
- K'a le ba won mimo gba
- Isimi.
- AMIN
CAC HYMN 149
Ji Wo Kristian
CAC Hymn 149
Ji Wo Kristian
- 1. Ji, 'wo Kristian, k'o ki oro ayo
- Ti a bi Olugbala araye;
- Dide, k'o korin ife Qlorun
- T'awon Angeli nko n'ijo kini;
- Lat' odo won n'ihin na ti bere:
- ihin Om'Olorun t'a bi s'aye.
- -
- 2. 'Gba na l'a ran akede angeli;
- T'a so f'awon olus'agutan pe,
- “Mo mu 'hinrere Olugbala wa
- T'a bi fun yin ati gbogbo aye,
- Olorun mu l'eri Re se loni
- A bi Olugbala, Krist' Oluwa.
- -
- 3. Bi akede angel' na ti so tan,
- Opolopo ogun orun si de;
- Won nkorin ayo t'eti ko gbo ri,
- Orin Aleluya gba orun kan,
- Ogo ni f'Olorun l'oke orun,
- Alafia at'ife s'eniyan.
- -
- 4. A ba le ma ranti nigbagbogbo
- Pe, 'fe Olorun l'o gba 'raye la,
- K'a to 'se Jesu t'o ra wa pada,
- Lat' ibuj' eran dor' agbelebu;
- K'a toro or'-ofe k'a le te le,
- Titi ao tun r'oju Re Qlorun.
- -
- 5. Nigbana 'gba 'ba de orun lohun
- A o korin ayo t'irapada;
- Ogo Eni t'a bi fun wa loni,
- Y'o ma ran yi wa ka titi laelae;
- A o ma korin ife Re titi,
- Oba angeli, Oba eniyan.
- Amin
CAC HYMN 024
Loju Ale Gba T'orun Wo
CAC Hymn 024
Loju Ale Gba T'orun Wo
- 1. L'oju ale 'gba't orun wo,
- Won gbe abirun w'odo Re,
- Oniruru ni asisan won,
- Sugbon won f'ayo lo' le won
- -
- 2. Jesu a de l'oj' ale yi,
- A sun m'O t'awa t'arun wa,
- Bi a ko tile le 'ri O,
- Sugbon, a mo p'O sunmo wa.
- -
- 3. Olugbala, wo osi wa,
- Opo nsaisan, opo nk'edun,
- Opo ko ni 'fe si O to.
- Opo n'ife won si tutu.
- -
- 4. Opo ti ri p'asan l'aye
- Sibe nwon ko f'aye sile,
- Opo l'ore ba n'inu je,
- Sibe won ko fi O s'ore
- -
- 5. Ko s'okan ninu wa t'o pe
- Gbogbo wa si ni elese,
- Awon t'o si nsin O toto
- Mo ara won ni alaipe
- -
- 6. Sugbon Jesu, Olugbala,
- Eni bi awa ni 'Wo 'se
- 'Wo ti ri 'danwo bi awa
- 'Wo si ti mo ailera wa.
- -
- 7. Agbar' owo Re wa sibe,
- Ore Re si ni agbara,
- Gbo adura ale wa yi,
- Ni anu, wo gbogbo wa san.
- AMIN
CAC HYMN 823
Ona Ara Lolorun Wa
CAC Hymn 823
Ona Ara Lolorun Wa
- 1. Ona ara l'Olorun wa
- Ngba sise Re l'aye;
- A nri 'pase Re lor'okun,
- O ngun igbi l'esin.
- -
- 2. Ona Re, enikan ko mo,
- Awamaridi ni;
- O pa ise ijinle mo,
- Oba awon oba.
- -
- 3. Ma beru mo, eyin mimo,
- Orun to su be ni,
- O kun fun anu yo rojo
- Ibukun s'ori yin.
- -
- 4. Mase da Oluwa l'ejo
- Sugbon gbeke re le;
- 'Gbati o ro pe O nbinu,
- Inu Re yo si o.
- -
- 5. Ise Re fere ye wa na,
- Y'o ma han siwaju;
- Bi o tile koro loni,
- O mbo wa dun lola.
- -
- 6. Afoju ni alaigbagbo,
- Ko mo 'se Olorun;
- Olorun ni Olutumo,
- Y'O m'ona Re ye ni.
- Amin
CAC HYMN 227
Bi Kristi Ti Da Okan Mi Nide
CAC Hymn 227
Bi Kristi Ti Da Okan Mi Nide
- 1. Bi Krist' ti da okan mi nde,
- Aye mi ti dabi orun,
- Larin 'banuje at'aro
- Ayo ni lati mo Jesu,
- -
- Aleluya! ayo l'o je
- Pe, mo ti ri 'dariji gba,
- Ibikibi ti mo ba wa
- Ko s'ewu, Jesu wa nibe
- -
- 2. Mo ti ro pe orun jina
- Sugbpn nigbati Jesu de
- L'orun ti de 'nu okan mi,
- Nibe ni y'o si wa titi.
- -
- 3. Nibo l'a ko le gbe l'aye
- L'o r'oke tabi petele,
- L'ahere tabi agbala,
- Ko s'ewu, Jesu wa nibe
- Amin
CAC HYMN 723
Ha! Egbe Mi
CAC Hymn 723
Ha! Egbe Mi
- 1. Ha! egbe mi e w'asia
- Bi ti nfe lele!
- Ogun Jesu fere de na,
- A fere segun.
- -
- “D'odi mu, Emi fere de”
- Beni Jesu nwi,
- Ran 'dahun pada s'orun, pe
- “Awa o di mu.”
- -
- 2. Wo opo ogun ti mbo wa;
- Esu nko won bo;
- Awon alagbara nsubu,
- A fe damu tan!
- -
- 3. Wo asia Jesu ti nfe,
- Gbo ohun ipe;
- A o segun gbogbo ota
- Ni oruko Re
- -
- 4. Ogun ngbona girigiri,
- Iranwo wa mbo;
- Balogun wa mbo wa tete,
- Egbe, tujuka!
- Amin.
CAC HYMN 746
Mofi Gbogbo Re Fun Jesu
CAC Hymn 746
Mofi Gbogbo Re Fun Jesu
- 1. Mo fi gbogbo re fun Jesu
- Patapata, laiku 'kan;
- Uno ma fe, uno si gbekele,
- Uno wa l'odo Re titi.
- -
- Mo fi gbogbo re,
- Fun O, Olugbala mi, ni
- Mo fi won sile.
- -
- 2. Mo fi gbogbo re fun Jesu,
- Mo fi 'rele wole fun;
- Mo fi 'gbadun aye sile,
- Gba mi, Jesu, si gba mi.
- -
- 3. Mo fi gbogbo re fun Jesu,
- Se mi ni Tire nikan;
- Je ki nkun fun Emi Mimo,
- Ki nmo pe, 'Wo je t'emi.
- -
- 4. Mo fi gbogbo re fun Jesu,
- Mo fi ara mi fun O;
- Fi 'fe at'agbara kun mi,
- Ki 'bukun Re ba le mi.
- -
- 5. Mo fi gbogbo re fun Jesu,
- Mo mo p'Emi ba le mi;
- A! ayo igbala kikun;
- Ogo, ogo, f'oko Re.
- Amin
CAC HYMN 635
Yio Dahun Gbogbo Adura
CAC Hymn 635
Yio Dahun Gbogbo Adura
- 1. Y'o dahun gbogb' adura
- Ileri ati 'fe Re
- Ko sa ti yi pada ri;
- Ogo f'oko Re
- -
- 2. Y'o dahun gbogb' adura
- Uno ro mo ileri Re
- Mo mo On ko je da mi
- Ogo f'oko Re.
- -
- 3. Y'o dahun gbogb'adura
- Je ka bere ni 'gbagbo
- Emi Re nran ni lowo
- Ogo foko Re
- -
- 4. Y'o dahun gbogb' adura
- Wa sibi ite anu
- O ri idaniloju
- Ogo foko Re
- Amin.
CAC HYMN 656
Ojo Ibukun Ro Si Ro
CAC Hymn 656
Ojo Ibukun Ro Si Ro
- 1. Ojo ibukun y'o si ro;”
- Ileri ife l'eyi
- A o ni itura didun
- Lat' odo Olugbala
- -
- Ojo ibukun,
- Ojo ibukun l'a nfe,
- Iri anu nse yi wa ka
- Sugbon ojo l'antoro.
- -
- 2. “Ojo ibukun y'o si ro,”
- Isoji iyebiye;
- L'ori oke on petele
- Iro opo ojo mbo
- -
- 3. “Ojo ibukun y'o si ro,'
- Ran won si wa, Oluwa;
- Fun wa ni itura didun
- Wa f'ola fun oro Re
- -
- 4. “Ojo ibukun y'o si ro,”
- Iba je le ro loni!
- B'a ti njewo f'Olorun wa
- T'a npe oruko Jesu.
- -
- Ojo ibukun,
- Ojo ibukun l'a nfe,
- Iri anu nse yi wa ka
- Sugbon ojo l'antoro.
- Amin.
CAC HYMN 587
Ma Koja Mi Olugbala
CAC Hymn 587
Ma Koja Mi Olugbala
- 1. Ma koja mi, Olugbala
- Gbo adura mi;
- 'Gbat' Iwo ba np' elomlran,
- Mase koja mi.
- -
- Jesu, Jesu, gbo adura mi
- 'Gbat' Iwo ba np'elomiran,
- Mase koju mi.
- -
- 2. N'ite anu, Je k'emi ri
- Itura didun,
- T'edun t'edun ni mo wole
- Jo, ran mi lowo
- -
- 3. N'igbekele itoye Re
- L'em' o w'oju Re;
- Wo 'banuje okan mi san,
- F'ife Re gba mi.
- -
- 4.'Wo orisun itunu mi,
- Ju 'ye fun mi lo,
- Tani mo ni l'aye lorun
- Bikose iwo?
- Amin.
CAC HYMN 241
Olugbala Gbohun Mi
CAC Hymn 241
Olugbala Gbohun Mi
- 1. Olugbala, gb'ohun mi
- Gb'ohun mi, gb'ohun mi,
- Mo wa s'odo Re, gba mi,
- Nibi agbelebu di
- Emi se sugbon Oku;
- Iwo ku, Iwo ku,
- Fi anu Re pa mi mo
- Nibi agbelebu,
- -
- Oluwa, jo gba mi,
- Nki y'o bi O ninu mo!
- Alabukun, gba mi
- Nibi agbelebu.
- -
- 2. Ese mi po lapoju
- Uno bebe, un o bebe!
- Iwo li Ona iye,
- Nibi agbelebu,
- Ore-ofe Re t'a gba,
- L'ofeni! L'ofeni;
- F'oju anu Re wo mi,
- N'ibi agbelebu.
- -
- 3. F'eje mimo Re we mi,
- Fi we mi! fi we mi!
- Ri mi sinu ibu Re,
- N'ibi agbelebu
- 'Gbagbo l'o le fun wa ni
- Dariji Dariji
- Mo f'igbagbo ro mo O
- N'ibi agbelebu.
- Amin.
CAC HYMN 208
Oluwa Ran Mi Nise Alleluia
CAC Hymn 208
Oluwa Ran Mi Nise Alleluia
- 1. Oluwa ran mi ni 'se, Aleluya!
- Iwo ni uno je ise na fun;
- A ko s'inu Oro Re, Aleluya!
- P'eni t'o ba wo Jesu y'o ye.
- -
- Wo, k'o ye, Arakunrin,
- Wo Jesu ki o si ye,
- A ko s'inu Oro Re, Aleluya!
- P'eni t'o ba wo Jesu y'o ye.
- -
- 2. A ran mi n'ise ayo, Aleluya!
- Uno j'isena fun o ore mi;
- Ise lat' oke wa ni; Aleluya!
- Jesu SO, mo mo pe oto ni.
- -
- 3. A n'owo iye si O, Aleluya!
- A o fi 'ye ailopin fun O;
- T'o ba wo Jesu nikan, Aleluya!
- Wo o, On nikan l'o le gbala. .
- Amin